Itan Igbesi Aye Baba Ijo CAC Aremo. Chief Oladosu Ajuwon

Igba meta nigba eda laye, igba owuro, osan ati  igba ale. Adura gbogbo eniyan nipe ki ojo ale sanwa ju igba yo Ku lo.

Nigbati awon eniyan kan je omobolanle, opolopo lo je pe ise owo eni ni gbeniga Loro tiwon.

Eyi gann loro to dara ju lati  sapejuwe Baba Abraham Oladosu Ajuwon bi won se fori ti gbogbo awon nkan ti a le se apejuwe bi idojuko ti won si di eniti nba oba jeun

Won bi baba Abraham Oladosu Ajuwon ni ogbon ojo osun kefa odun 1932 sinu idile baba Gabriel Kolapo Ajuwon Lati Abule Agbongun  ni ilu Ibadan, aba yi lowa ni ijoba ibile Akinyele ni ipinle Oyo.

Baba won, eeyun baba Gabriel Kolapo Ajuwon si ni onigbagbo akoko ni abule Agbongun nigba ti a nwi yi.

Baba Oladosu Ajuwon bere ile iwe alakobere  ti won npe ni standard nigbana ni odun 1942, sugbon bi won se nife to lati kawe iku baba won ni odun 1946 mu ifaseyin to lagbara ba erongba won latikawe.

Baba Oladosu Ajuwon wa ni ipele Kerin (standard 4) nigbati baba won Ku, se Yoruba ni ma se bi Iya kiise ya, n se bi baba kiise bi baba, bayi gan loro seri nigbati awon ebi baba won mori wole, leyin iku baba won, eyi lo si fa ti baba Ajuwon se joko sile fun odidi odun kan latari aisi owo lati San fun ile iwe.

Leyin odun kan ti baba Ajuwon ti wa nile,  ni ijo St. John Anglican Church, Igbo Oloyin to ni ile iwe ti baba nlo nigba na fun ni ebun eko ofe, lati pari eko alakobere..

Bayi ni won pada si ile iwe ni odun 1947. Bi asa nigbana, nigbati akeko kan bade ipele kefa, ( standard 6) yo kuro loko, bayi ni baba Ajuwon se fi Igbo Oloyin sile, lati wa pari eko alakobere ni eka ile eko na to wa ni mapo, St. John School Mapo ni odun 1949 Ijo na lo di Christ’s Church Mapo bayi.

Igbesi aye tuntun yi se ajeji pupo si  Baba Dosu, to o si o fere pada si abule latari ohun ti awon omo igboro fi oju won ri nigbana lohun, sugbon lati iwa jeje ati bi o se je onisuru eniyan, awon oluko won nigbana lolorun fi  se olugbeja

Yato si iriri omo oko to wa sile, Baba Ajuwon je enikan to ma nrera,eyi si tun WA lara bi o se le die fun lati gbagbe Abule Agbongun nitori funra re ni yo dana onje ti yo je nigba to ba ti ile iwe de, ajeku onje yi na si ni yo gbe kana ni ojo keji to ba nlo si ile owe.

Ojo kedogun kedogun ni Oladosu ma nlosi Agbongun, ese si niyo firin lati Mapo lo si Abule Agbongun, Lona Ojoo, bosi Pade, lati bosi Aroro si Igbo Oloyin. (fun eniti ko mo bi Abule Agbongun se ri si Mapo)

Leyin ti baba Dosu Ajuwon pari ile iwe Standard ni Odun 1949 won ni admission si Junior Technical School Yaba ni ilu eko, sugbon oda owo awo olokun tun ja won ni tanmoo, won ko leelo nitori ko si owo,  eyi lo mu won ko ise ile kiko lodo okunrin agbase se kan to nje keru ni agbegbe Ekotedo ilu Ibadan.

Lehin ti Baba Abraham Dosu Ajuwon pari ise kiko ni Odun 1959 loda ile ise tiwon sile ti won sigba opolopo sise.

SPIRITUAL LIFE.

Lehin ti Baba Dosu Ajuwon kuro ni Abule Igbo Oloyin lo wa si igboro, Agboole won ni agboole AGbongun ni won de si ni Aremo eyi lo si fa ti won ko fi le ma tesiwaju mo pelu ijo Anglican ti won nlo ni oko Igbo Oloyin, bayi si ni won dara po mo Ijo Aposteli ti Kristi, Christ Apostolic Church, Ita Baale OLUGBODE, Lara ohun to tun je ki eyi ya ni pe, enikan Pataki ni ilu Ibadan, o da, ki akuku soju abe niko Olubadan igbanaa, Oba Isaac Akinyele ti o ngbe ni adugbo kanna, pelu won, ti won tun wa je okan lara Alufa Ijo yi, je ki IFE won fa si lati darapo mo ijo yi.

Didarapo ti won darapo mo ijo yi fun won ni anfani lati sunmo Oba Akinyele, ti won si je okan Lara awon odo ti Olubadan feran nitori ifokansin won fun ise Oluwa.

Ninu ijo yi na si ni baba ti ba Jesu pade ti won si GBA Emi Mimo ni odun 1957

Ni odun 1959 Baba Dosu Ajuwon kuro ninu Ijo CAC itabale Olugbode to si darapo mo ijo CAC ti won sese da sile ni agbegbe Aremo.

Lehin ti Baba di omo ijo CAC Oke Igbala Aremo, o je adari egbe odo, ti osi tun di oga Akorin ninu ijo yii . Awon so tun ni Akowe Ijo akoko ni CAC Aremo

Ninu ijo yi gan na si tun ni Baba ti ri iyawo ti won si se igbeyawo ni odun 1961.

Ni odun 1976 ni baba Joye Alagba ninu ijo yi ti OSI di baba Ijo CAC Oke Igbala Aremo ni odun 2010.

Ya to si ise takuntakun ti Baba  se ninu Ijo Aremo, Ijo CAC lapapo kole gbagbe ise ribiribi ti Abraham Oladosu Ajuwon se lati ri daju pe, Ijo CAC ndagba soke.

Ni Odun 1997, Baale aba Eniosa fi Baba Abraham  Oladosu Ajuwon je Jagunmolu to Eniosa Lati mo riri takun takun  to won ti se fun  idagbasoke ilena.

Baba Oladosu Ajuwon tun se idasile Dosu Ajuwon Foundation ti won first ntoju awon opo ati alaini

Titi di oni Baba Abraham Oladosu Ajuwon so ntesiwaju ninu sinsin Oluwa ati omoniyan pelu mimu Idagbasoke baadugbo at I ile Ibadan lapapo.

Leave a Comment